Testo Jagun Jagun - BANTU
Testo della canzone Jagun Jagun (BANTU), tratta dall'album Everybody Get Agenda
Jagun-jagun ló ń bọ̀
Jagun-jagun ló ń bọ̀
Jagun-jagun ló ń bọ̀
Olórí-ogun ò gbọdọ̀ kẹ́yìn ogun
Ọ̀kan ṣoṣo Ẹja tí ń d'abú-omi rú
Ọ̀kan ṣoṣo Ẹfọ̀n tí ń d'ọ̀dàn rú
Ọ̀kan ṣoṣo Àjànàkú tí ń m'igbó kìji-kìji
Jagun-jagun dé, ọmọ ọba kìí jagun bí ẹrú
Òlọ́ṣọmọ́dìí gba ìbọn lọ́wọ́ ọmọ ojo
Jagun-jagun, afiwájúgbọta, afẹ̀yìngbọfà
Jagun-jagun ò fẹ́rọ̀, alágbára èyàn tí ń fi májèlé ròfọ́
Àlùjànú èyàn tí ń fi ọmọ-odó tayín
Bó ṣe ń bá ọmọdé ṣe, bẹ́ẹ̀ ló ń bágbà ṣe
Kọ̀nàn-kọ̀nàn já tòun tòwú
Jagun-aso, ẹkùn ọkọ òkè!
Arọnimaja ṣáagun!
Ó ṣáagun ṣáagun, ó ṣáagun títí
Ohun l'awo Alágbàá'a, èyí tí ó fi ta b'aṣeégún lójú
Jagun-jagun ló ń bọ̀
Jagun-jagun ló ń bọ̀
Jagun-jagun ló ń bọ̀
Credits
Writer(s): Adegoke Odukoya, Abiodun Oke, Akin Akinhanmi, Akinkunmi Olagunju, Ayomiku Aigbokhan, Babajide Okegbenro, Dare Odede, Isaiah Odeyale, Olufemi Sanni, Opeyemi Oyewande, Peter Sadibo, Damilola Williams, Ibrahim Oyetunji, Laolu Ajibade
Lyrics powered by www.musixmatch.com
Link
Disclaimer:
i testi sono forniti da Musixmatch.
Per richieste di variazioni o rimozioni è possibile contattare
direttamente Musixmatch nel caso tu sia
un artista o
un publisher.